
Bi oseku die ki awe awon musulumi ti odun yi wa si opin, ipe
ti losi odo gbogbo omo orile ede Naijiria
lati fi owo sowopo pelu ijoba to wa lori alefa lati gbimopo segun awon
agbe sunmomi ti won nda omi alaafia ru
Agba oje lori oro eto abo ti osi tunje alaga egbe PCRC ni
agbegbe moniya ni ijoba ibile akinyele, oloye olaiya babalola ti awon eniyan
tunmo si “koyewon” ni o pasamo oro yi nigba ti o n fi oro jomitoro oro pelu iwe
iroyin bodeseri lori ero ibanisoro GSM.
Oloye koyewon eni ti
otun je are ona kakanfo fun egbe man o war ni ipinle oyo so lasoye pe niwon
igbati ijoba apapo ti mo ojuse re lori oro abo ti osi tun ti gbe gbogbo igese
to peye oti wa di oranyan fun tolori telemu orile ede yi lati fi owo sowopo ri
eyin awon agbe sunmomi lawujo wa.
Oloye koyewon ko saifi idunnu re han lori bi awon omo egbe
PCRC ti ekun moniya se nfi owo sowopo pelu awon agbofinro agbegbe na , o wa
jeje wipe ijoba ohun koni karee lati ri pe iwa odaran dinku patapata ni ekun moniya.
Nigbati o nki gbogbo awon musulumi jake jado ori igun
mererin agbaye fun ti awe ramadan ti odun yi ti o pari.
Oloye koyewon ro won lati ma mu eko ti won ko ninu osu
ramadan lo, ki won si ma wa ojurere allah lori gbogbo idawole won lojojumo.